HYMN 366

H.C 242 6s (FE 388)
"Ninu ile Baba mi, opolopo 
ibugbe lo wa" - John 14:21. ILE bukun kan wa 

   Lehin aiye wa yi

   Wahala, irora 

   At'ekun ki de ‘be 

   lgbagbo y'o dopin 

   Ao de 'reti l‘ade 

   Imole ailopin

   Ni gbogbo ibe je.


2. Ile kan si tun mbe 

   Ile alafia

   Awon Angel rere 

   Nkorin n‘nu re lailai 

   Y‘ite ogo Re ka 

   L‘awon egbe mimo 

   Nwole nwon nteriba 

   F'Eni Metalokan.


3. Ayo won ti po to! 

   Awon to ri Jesu 

   Nibit’o gbe gunwa 

   T‘a si nfi ogo fun 

   Nwon nkorin iyin Re

   At t’ isegun Re

   Nwon ko dekun rohin 

   Ohun nla t'o ti se.


4. W'Oke, enyin mimo 

   E le iberu lo

   Ona hiha kanna 

   L’Olugbala ti gba

   E fi suru duro

   Fun igba die sa

   Terin-terin l’On o

   Fi gba nyin sodo Re. Amin

English »

Update Hymn