HYMN 368

H.C 239 C.M (FE 390)
"O si fi ilu ni han mi, Jerusalem
Mimo" - lfihan 21:101. JERUSALEMU ibi ayo

   T’o se owon fun mi 

   ‘Gbawo n'ise mi o pari 

   L'ayo l'alafia.


2. Gbawo ni oju mi y‘o ri 

   Enu bode pearl Re? 

   Odi re t‘o le fun ‘gbala 

   Ita wura didan.


3. Gbawo, ilu Olorun mi 

   L’emi o d‘afin Re? 

   Nibiti Ijo ki ‘tuka 

   N‘ib’ayo ailopin.


4. Ese t'emi o ko iya 

   lku at'iponju

   Mo nwo ile rere Kenaan 

   Ile ‘mole titi.


5. Aposteli, Martyr, Woli 

   Nwon y’Olugbala ka 

   Awa tikara wa, fere 

   Dapo mo ogun na.


6. Jerusalem ilu ayo 

   Okan mi nfa si O

   ‘Gbati mo ba ri ayo re 

   lse mi y’o pari. Amin

English »

Update Hymn