HYMN 373

(FE 395) C.M.S 260, H.C 532 P.M
"Mo ni ife ati lo, ki emi le wa lodo 
Kristi" - Filippi 1:23
Tune: Gbo Orin Eni Rapada1. PARADISE! Paradise! 

   Tani ko fe simi?

   Tani ko fe ‘le ayo na 

   lle alabukun.

Egbe: Nib'awon oloto

      Wa lai ninu ‘mole 

      Nwon nyo nigbagbogbo 

      Niwaju Olorun.


2. Paradise! Paradise! 

   Aiye ndarugbo lo 

   Tani ko si fe lo simi 

   Nib' ife tutu?

Egbe: Nib'awon oloto...


3. Paradise! Paradise! 

   Aiye yi ma su mi! 

   Okan mi nfa sodo Jesu 

   Emi nfe r'oju Re.

Egbe: Nib'awon oloto...


4. Paradise! Paradise!

   Mo fe ki nye dese

   Mo fe ki nwa lodo Jesu,

   Li ebute mimo. 

Egbe: Nib'awon oloto...


5. Paradise! Paradise!

   Nko ni duro pe mo 

   Nisiyi b'eni pe mo ngbo 

   Ohun orin orun.

Egbe: Nib'awon oloto

      Wa lai ninu ‘mole 

      Nwon nyo nigbagbogbo 

      Niwaju Olorun. Amin

English »

Update Hymn