HYMN 374

S.1131 (FE 396)
“So itan kanna fun mi"1. SO itan kanna fun mi 

   T'ohun ti mbe lorun 

   Ti Jesu on Ogo Re 

   Ti Jesu on ‘Fe Re

    So ‘tan na ye mi daju 

    B’o ba ti so f'ewe 

    Nitori emi ko l‘okun 

    Mo si je l'elese.


2. So‘tan na fun mi pele 

   Ki o ba Ie ye mi

   Ti Iyanu Irapada 

   T'etutu fun ese

    So fun mi nigbagbogbo 

    Nitori nko fe gbagbe 

    Ero mi si nfe lati gbo 

    Orin adidun na.


3. So itan kanna fun mi 

   N’igbat’O ba ri pe

   Ogo asan aiye yi, 

   Fe gba mi li okan

    Gba t‘Ogo oke orun

    Ba si nfara han mi
 
    So ‘tan kanna fun mi pe, 

    Krist’ mu o larada. Amin

English »

Update Hymn