HYMN 383

H.C 6s 8s (FE 405)
"Emi Olorun si nrababa loju omi"
 - Gen. 1:2
1. EMI Eleda nipa Re

   L‘a f‘ipile aiye sole

   Masai be gbogbo okan wo, 

   Fi ayo re si okan wa

   Yo wa nin‘ese at’egbe

   K'o fi wa se ibugbe Re.


2. Orisun imole ni O

   Ti Baba ti se ileri

   lwo Ina mimo orun

   Fi ‘fe orun kun okan wa 

   Jo tu ororo mimo Re 

   Sori wa bi a ti nkorin.


3. Da opo ore-ofe Re 

   Lat’orun sori gbogbo wa 

   Je k'a gba otito Re gbo 

   K'a si ma sa ro l'okan wa 

   F’ara Re han wa k’a le ri 

   Baba at‘Omo ninu Re.


4. K‘a fi ola ati iyin

   Fun baba Olodumare

   K'a yin oko Jesu logo 

   Enit’o ku lati gba wa 

   Iyin bakanna ni fun O 

   Parakliti Aiyeraiye. Amin

English »

Update Hymn