HYMN 384

(FE 406)
C.M.S 279 H.C 262 t. A & M
470 7s 6s
“Emi o dabi iri si Israel" - Hos. 14:51. EMI ‘bukun ti a nsin 

   Pelu baba at'oro 

   Olorun aiyeraiye 

   Emi Mimo, gbo tiwa.


2. Emi Mimo ‘Daba orun 

   Irti ri nse lat‘oke

   Emi ‘ye at’ina fe 

   Emi Mimo, gbo tiwa.


3. lsun ipa at’imo 

   Ogbon at'iwa mimo 

   Oye, imoran, eru 

   Emi Mimo, gbo tiwa.


4. lsun ife, alafia

   Suru, ibisi ‘gbagbo 

   Reti, ayo ti ki tan 

   Emi Mimo, gbo tiwa.


5. Emi afonahan ni 

   Emi ti nmu ‘mole wa 

   Emi agbara gbogbo 

   Emi Mimo, gbo tiwa.


6. ‘Wo t'o mu Wundia bi, 

   Eni t'orun t'aiye mbo 

   T'a ran lati tun wa bi 

   Emi Mimo, gbo tiwa.


7. ‘Wo ti Jesu t'oke ran

   Wa tu enia Re ninu

   Ki nwon ma ba nikan wa, 

   Emi Mimo, gbo tiwa.


8. Wo t’o nf'ore kun ljo 

   T’o nfi ife Baba han 

   T'O nmu k‘o ma ri Jesu 

   Emi Mimo, gbo tiwa.


9. F‘ebun meje Re fun ni 

   Ogbon lati m'Olorun 

   lpa lati ko ota

   Emi Mimo, gbo tiwa.


10. Pa ese run lokan wa, 

   To ife wa si ona

   Gba ba nse O, mu suru 

   Emi Mimo, gbo tiwa.


11. Gbe wa dide b'a subu 

    Ati nigba idanwo

   Sa pe wa pada pele

   Emi Mimo, gbo tiwa.


12. Wa, k'O mu ailera le 

    F'igboiya fun alare 

    Ko wa l’oro t'a o so 

    Emi Mimo, gbo tiwa.


13. Wa ran okan wa lowo 

    Lati mo otito Re

    Ki‘ fe wa Ie ma gbona 

    Emi Mimo, gbo tiwa.


14. Pa wa mo l‘ona toro 

    Ba wa wi nigb’a nsako 

    Ba wa bebe l’adura 

    Emi Mimo, gbo tiwa.


15. Eni Mimo Olufe

    Wa gbe inu okan wa 

    Ma fi wa sile titi 

    Emi Mimo, gbo tiwa. Amin

English »

Update Hymn