HYMN 387

H.C 261 8.6.8.4 (FE 410)
"Emi o si bere Iowo Baba, on o si fun 
nyin li Olutunu miran, ki o le ma 
bo nyin gbe titi" - John 14:161. OLURAPADA wa k’On to

   Dagbere ikehin
 
   O fi Olutunu fun ni 

   Ti mba wa gbe.


2. O wa ni awo adaba 

   O na iye bo wa

   O tan ‘fe on alafia 

   Sori aiye.


3. O de, o mu ‘wa-rere wa, 

   Alejo Olore,

   Gbat' o ba r'okan irele 

   Lati ma gbe.


4. Tire l'ohun jeje t’a ngbo 

   Ohun kelekele

   Ti ngbaniwi, ti nl’eru lo 

   Ti nso t‘orun.


5. Gbogho iwa‐rere t‘a nhu 

   Gbogbo isegun wa 

   Gbogbo ero iwa-mimo 

   Tire ni won.


6. Emi Mimo Olutunu 

   F'iyonu be wa wo

   Jo, s’okan wa n’ibugbe Re 

   K‘o ye fun O. Amin

English »

Update Hymn