HYMN 389

(FE 412) H.C 265 t.H.C 131 6s 4s
“Tani ki o beru re, Oluwa, ti ki yio si fi ogo
fun oruko Re? nitoripe Iwo nikansoso ni
mimo" - Ifi 15:4


1. BABA oke orun 

   T’imole at’ife 

   Eni gbani

   Mole t‘a ko le wo

   Ife t’a ko le so 

   Iwo Oba airi 

   Awa yin O.


2. Kristi Omo lailai 

   Wo t’o di enia 

   Olugbala 

   Eni giga julo 

   Olorun, lmole 

   Aida at‘Ailopin

   A kepe O.


3. Iwo Emi Mimo 

   T’ina Pentikost‘ Re

   Ntan titi lai

   Masai tu wa ninu

   L'aiye aginju yi

   Wo l'a fe 'Wo l'a nyin 

   Ajuba Re.


4. Angel' e lu duru

  K'orin t'awa ti nyin 

  Jumo dalu

  Ogo fun Olorun

  Metalokansoso

  A yin O tit'aiye

  Ainipekun. Amin

English »

Update Hymn