HYMN 39

C.M.S. 38, C.H 224 7s (FE 56)
"Nitoripe awa ti o gbagbo nwo 
inu isimi” - Heb. 4:3


1. K‘OJO ‘simi yi to tan 

   K' a to lo f’ara le ‘le, 

   Awa wole l’ese Re, 

   A nkorin iyin si O.


2. Fun anu ojo oni,

   Fun isimi Iona wa,

   ‘Wo nikan l‘a f’ope fun 

   Oluwa at'oba wa.


3. lsin wa ko nilari

   Adura wa lu m‘ese 

  Sugbon ‘Wo l‘o nf’ese ji, 

  Or'ofe Re to fun wa.


4. Je k‘ife Re ma to wa 

   B‘a ti nrin ‘na aiye yi:' 

   Nigbat‘ajo wa ba pin 

   K’a le simi lodo Re.


5. K'ojo ‘simi wonyi je 

   lbere ayo orun;

   B'a ti nrin ajo wa lo, 

   S'isimi ti ko l'opin. Amin

English »

Update Hymn