HYMN 399

(FE 422)
H.C. 2nd Ed 263 t.H.C 8s. 7s 6s
'Oro re ni fitila fun ese mi" - Ps. 119:1051. IWO Oro Olorun 

   Ogbon at'oke wa

   Oto ti ki yipada 

   Imole aiye wa

   Awa yin O fun ‘mole 

   T‘inu lwe mimo 

   Fitila fun ese wa

   Ti ntan titi aiye.


2. Oluwa l’o f’ebun yi 

   Fun ljo Re l’aiye

   A ngbe ‘mole na soke 

   Lati tan y’aiye ka

   Apoti wura n’ise 

   O kun fun Otito 

   Aworan kristi si ni 

   Oro iye toto.


3. O nfe lele b’asia

   T’a ta loju ogun

   O ntan b’ina alore

   Si okunkun aiye 

   Amona enia ni

   Ni wahala gbogbo 

   Nin’arin omi aiye
 
   O mo wa sodo Kristi.


4. Olugbala, se ‘jo Re 

   Ni fitila wura

   Lati tan imole Re 

   B’aiye igbani

   Ko awon ti o sako

   Lati lo ‘mole yi

   Tit‘okun aiye y’o pin

   Ti nwon o r’oju Re. Amin

English »

Update Hymn