HYMN 401

C.M (FE 424)
"Emi o tu Emi mi jade si ara enia
gbogbo" - Joeli 2:281. EMI Mimo, mi s'okan wa, 

   K'a mo agbara Re

   Orisun emi ‘sotele 

   T‘imole at'ife.


2. Emi Mimo, l'agbara Re 

   L’awon woli sise

   lwo l’o nfi oto han wa 

   Ninu iwe mimo.


3. Adaba orun, na ‘ye Re 

   Bo okun eda wa

   Jeki mole Re tan sori 

   Emi aisoto wa.


4. A o mo Olorun daju 

   B’lwo ba mbe n‘nu wa 

   A o mo ‘jinle ife mimo 

   Pelu awon Tire. Amin

English »

Update Hymn