HYMN 402

H.C 601 8s 7s (FE 425)
"Nitori mi ati nitori ihinrere" - Marku 8:351. ‘Tori Mi at’lhinrere 

   E lo so t‘irapada

   Awon onse Re nke Amin!

   Tire ni gbogbo ogo

   Nwon nso t'ibi, t’iya, t’iku 

   Ife etutu nla Re

   Nwon ka ohun aiye s’ofo 

   T' ajinde on 'joba Re.


2. Gbo, gbo ipe ti Jubili

   O ndun yi gbogbo aiye ka 

   N’ile ati l'oju okun

   A ntan ihin igbala 

  Bi ojo na ti nsumole 

  T‘ogun si ngbona janjan

  Imole ila-orun na

  Y’o mo Iarin okunkun.


3. Siwaju ati siwaju

   Lao ma gbo Halleluya 

   Ijo ajagun y'o ma yo 

   Pe l’awon oku mimo

   A fo aso won n’nu eje 

   Duru wura won si ndun 

   Aiye at'orun d’ohun po 

   Nwon nko orin isegun.


4. O de, Enit’ a nw’ona Re 

   Eni ikehin na de, 

   lmmanueli t'o d’ade 

   Oluwa awon mimo 

   lye, Imole at'Ife 

   Metalokan titi lai

   Tire ni ite Olorun

   Ati t’Odo-aguntan. Amin

English »

Update Hymn