HYMN 41

C.M.S.39, H.C. 15, L.M (FE 58)
“Emi o tu Emi mi jade sara, 
gbogbo enia" - lse 2:171. EMI Olorun alaye 

   N‘nu ekun ore-ofe Re, 

   Nibit‘ ese enia ti te 

   Sokale sori iran wa.


2. F’ebun ahon, okan ife, 

   Fun wa lati soro ‘fe Re, 

   K‘ibukun at’agbara Re, 

   Ba l‘awon t'o ngbo oro na.


3. K’okun kase ni bibo Re; 

   Ki darudapo di tito 

   F‘ilera f'okan ailera 

   Jeki anu bori ibinu.


4. Emi Olorun, jo pese 

   Gbogbo aiye fun Oluwa;

   Mi si won b' afefe oro 

   K'okan okuta le soji.


5. Baptis' gbogb' orile-ede

   Rohin ‘segun Jesu yika

   Yin Oruko Jesu logo

  Tit‘araiye yio jewo Re. Amin

English »

Update Hymn