HYMN 411

(FE 433) C.M.S 259 t.H.C 247 DSM 
Tune: "Lehin odun die”1. OLORUN Serafu

   Ati ti Kerubu

   Masai pelu awa t’aiye 

   Ko gbo adura.

Egbe: Alanu Olore

      Gbo tiwa Baba wa

      Iwo to gbo ti Elijah 

      Gbo t’Egbe Serafu.


2. lwo Omo Baba

   T’o ti gb’ara wa wo 

   lwo ti mo ailera wa 

   Ma wa fun wa titi.

Egbe: Alanu Olore...


3. Ise ‘yanu Re yo

   Larin Igbimo wa

   T’o gbe Alagba wa dide 

   Fun igbala enia.

Egbe: Alanu Olore...


4. Ope ni f ’Olorun

   Fun ‘ru ore Re yi

   Ti ko ka wa s’alailera 

   To nfi ran re han wa. 

Egbe: Alanu Olore...


5. Ebun rere re ni

   To ti pese fun wa

   A mbe O Baba wa orun 

   Mase je ko ya wa.

Egbe: Alanu Olore...


6. E f‘Ogo fun Baba

   E f'Ogo fun Omo

   E f‘Ogo fun Emi Mimo 

   Metalokan lailai.

Egbe: Alanu Olore

      Gbo tiwa Baba wa

      Iwo to gbo ti Elijah 

      Gbo t’Egbe Serafu. Amin

English »

Update Hymn