HYMN 412

H.C. 273 D. 7s 6s (FE 434)
"E ma gbadura li aisimi" - 1 Tess. 5:171. LO l’oro kutukutu 

   Lo, ni osangangan 

   Lo, ni igba asale 

   Lo ni oganjo oru, 

   Lo, t’iwo t’inu rere 

   Gbagbe ohun aiye 

   Si kunle n’iyewu re 

   Gbadura nikoko.


2. Ranti awon t’o fe o 

   At' awon t'iwo fe 

   Awon t‘o korira re

   Si gbadura fun won 

   Lehin na, toro ‘bukun 

   Fun ‘wo tikalare 

   Ninu adura re, ma

   Pe oruko Jesu.


3. B’aiye ati gbadura 

   Ni koko ko si si

   T'okan re fe gbadura 

   Gbat’ore yi o ka 

   Ghana, adura jeje 

   Lat’ inu okan re

   Y’o de odo Olorun 

   Olorun Alanu.


4. Ko si ay, kan l’aiye 

   T’o si ju eyi lo

   Nit' agbara t'a fun wa 

   Lati ma gbadura

   ‘Gba t’inu re ko ba dun 

   Jek‘okan re wole

   Ninu ayo re gbogbo 

   Ranti or'ofe re. Amin

English »

Update Hymn