HYMN 414

(FE 437)
"Akanse orin fun adura awon aboyun, 
omo were ati awon ti nwoju Oluwa"
Tune: Jesu ni Balogun oko
1. JESU lo ngbebi aboyun

   E mase jek' a foiya

   Olugbala wa ni Jesu

   E mase je k'a foiya.

Egbe: E mase beru

      E kun fun ayo

      Nitori Jesu ni Oba wa

      B'o ti wu k'iji na leto

      Y’o da wa sile Iayo.


2. Enyin aboyun Serafu 

   E kepe Jesu nikan

   K'e si gbeke nyin le pelu 

   Y'o da nyin sile l'ayo

Egbe: E mase beru...


3. Olugbala, ‘Wo ti ‘ya re 

   Ru O gba osu mesan 

   Ni bethlehem Judea 

   Layo ibi sokale.

Egbe: E mase beru...


4. Ki l’ohun ti mba nyin l‘eru 

   Enyin Omo ogun Kristi

   Gbati Jesu ti je tiwa

   Ayo ni yio je tiwa. 

Egbe: E mase beru...


5. Lowo, aje ati oso 

   Lowo ajakale arun

   Lowo lku, ekun, ose

   Jesu yio pa Tire mo. 

Egbe: E mase beru...


6. Metalokan Alagbara 

   Dabobo awon omo Re

   Lowo ota ati esu

   Jek’ awa k‘Alleluyah. 

Egbe: E mase beru...


7. Olorun to l’agan ninu 

   Y‘o gbo t’enyin ti ntoro

   B'O ti s‘ekun Hannah d‘erin

   Yo f’omo pa nyin l‘erin. 

Egbe: E mase beru...


8. Ogo ni fun Baba l‘oke 

   Ogo ni fun Omo Re

   Ogo ni fun Emi Mimo

   Metalokan l'ope ye.

Egbe: E mase beru

      E kun fun ayo

      Nitori Jesu ni Oba wa

      B'o ti wu k'iji na leto

      Y’o da wa sile Iayo. Amin

English »

Update Hymn