HYMN 415

S.48 L.D.L.M (FE 438)
“Wakati adura" - Ise 3:11. WAKATI adura didun!

   T‘o gbe mi lo kuro l'aiye 

   Lo'waju ite Baba mi

   Ki nso gbogbo edun mi fun

   Nigba ‘banuje at‘aro

   Adua l'abo fun okan mi

   Emi si bo lowo Esu

   'Gbati mo ba gb'adua didun

   Emi si bo lowo Esu

   'Gbati mo ba gb'adua didun. 


2. Wakati adura didun!

   Iye re y’o gbe ebe mi

   Lo sod’Enit’ o se ‘leri 

   Lati bukun okan adua

   B’O ti ko mi, ki nwoju Re 

   Ki ngbekele, ki nsi gbagbo 

   Ngo ko gbogb’aniyan mi le 

   Ni akoko adua didun.


3. Wakati adura didun!

   Jeki nma r’itunu re gba 

   Titi ngo fi d’oke Pisga

   T ngo r’ile mi l’okere 

   Ngo bo ago ara sile

   Ngo gba ere ainipekun

   Ngo korin bi mo ti nfo lo

   Odigbose! adua didun,

   Ngo korin bi mo ti nfo lo

   Odigbose! adua didun. Amin

English »

Update Hymn