HYMN 418

C.M.S 539 t.H.C 487.75s (FE 441) 
“Olorun si wipe, Bere ohun ti emi o 
fi fun O” - 1 Oba 3:5 (FE 441)1. MURA ebe okan mi 

   Jesu nfe gb’adura re 

   O tipe k’o gbadura 

   Nitorina yio gbo.


2. Lodo Oba n'iwo mbo 

   Wa lopolopo ebe

   Be l’ore-ofe Re po 

   Ko s’ eni ti bere ju.


3. Mo t’ibi eru bere 

   Gba mi ni eru ese

   Ki eje t’o ta sile 

   We ebi okan miu nu.


4. Sodo re mo wa simi 

   Oluwa gba aiya mi 

   Nibe ni ki O joko 

   Ma je Oba okan mi.


5. N’irin ajo mi l'aiye 

   K’ife Re ma tu mi n‘nu 

   Bi ore at’oluso

   Mu mi dopin irin mi.


6. F'ohun mo ni se han mi 

   Funmi l’otun ilera

   Mu mi wa ninu ‘gbagbo 

   Mu mi ku b‘enia Re. Amin

English »

Update Hymn