HYMN 42

H.C. 51, L.M (FE 59)
"lbukun Re mbe lara awon 
enia Re" - Ps. 3:81. IWO t'o nmu okan mole 

   Nipa 'mole atorunwa

   T'o si nse iri ibukun

   Sor‘awon ti nsaferi Re.


2. Jo masai fi ibukun Re, 

   Fun oluko at'akeko

   Ki ljo Re le je mimo 

   K’atupa re ma jo gere.


3. F‘okan mimo fun oluko, 

   lgbagbo, ‘reti, at'ife

   Ki nwon j'enit' lwo ti ko 

   Ki nwon le j‘oluko rere.


4. F'eti igboran f'akeko 

   Okan ‘rele at'aitetan

   Talaka to kun f‘ebun yi,

   San ju oba aiye yi lo.


5. Buk'oluso: buk'agutan, 

  Ki nwon j'oknn labe so Re,

  Ki nwon ma f’okan kan sona,

  Tit‘ aiye osi yi y‘o pin.


6. Baba, b‘awa ba n’ore Re, 

   Laiye yi l'a ti l’ogo

   K'a to koja s'oke orun 

   L'ao mo ohun ti aiku je. Amin

English »

Update Hymn