HYMN 422

C.M.S 571 t.S. 86 C.M. (FE 445) 
"Eda ara mi ko pamo kuro lodo Re"
- Ps. 139:151. TERUTERU t’iyanu ni 

   Olorun mi da mi 

   Gbogbo awon eya ara mi 

   Ise iyanu ni.


2. Nigbat' a da mi n’ikoko 

   O ti mo ara mi

   Eya ara mi l'O si mo 

   Sa t’okan won ko si.


3. Olorun, iro inu Re 

   Se ‘yebiye fun mi 

   Iye won poju iyanrin 

   Ti ko seni le ka.


4. B’o ti mo eda mi bayi 

   Wadi okan temi

   Mu mi mo ona Re lailai 

   Si ma to ese mi. Amin

English »

Update Hymn