HYMN 427

C.M.S 570 C.H. 98 t.H.C 138 C.M (FE 450)
"Nibo ni emi si gbe lo kuro Iowo 
emi Re?" - Ps.139:71. OLUWA, Iwo wadi mi 

   Em’ ise owo Re

   ljoko on idide mi

   Ko pamo loju Re.


2. N'ile mi, ati l’ona mi 

   N’ Iwo ti yi mi ka

   Ko s’iro tabi oro mi 

   T’Iwo ko ti mo tan.


3. Niwaju ati lehin mi 

   N’lwo ti se mi mo 

   Iru‘mo yi se ‘yanu ju 

   Ti emi ko le mo.


4. Lati sa kuro loju Re 

   ls’ asan ni fun mi 

   Emi Re lu aluja mi 

   Beni mo sa lasan.


5. Bi mo sa sinu okunkun 

   Asan ni eyi je

   Imole l’okunkun fun O 

   B’osangangan l’o ri.


6. Bi Iwo ti mo okan mi 

   Lat'inu iya mi

   Je ki emi k'o f'ara mi 

   Fun O Olugbala. Amin

English »

Update Hymn