HYMN 435

S.S 640 (FE 459)
"E fi Ogo fun Oruko Oluwa” - Ps. 96:81. EMI ko wa oro aiye 

   O pese f’aini mi, 

   Sugbon ngo noga siwaju 

   F‘oju to mu hanhan

   Ki ngbekele O Oluwa 

   F‘ore-ofe ojojumo. 

Egbe: Gbana l‘okan mi o korin 

      Labe agbelebu

      Nitori ‘simi dun l'ese Krist' 

      Gba mo fi ‘gbagbo re 'le

      Gba mo fi ‘gbagbo re 'le.


2. Nki y’o nani ohun aiye

   To o nrogba yi mi ka 

   Sugbon ngo f ’ayo sa ‘pa mi, 

   Iyoku d’owo Re

   O daju p’ere didun wa, 

   F’awon to simi l’Oluwa. 

Egbe: Gbana l‘okan mi o korin...


3. Ng’ ki y’o sa f‘agbelebu mi, 

   Ohun t'o wu k’ o je

   Sugbon ki nsa le wa fun O 

   Ki nsa se ife Re

   Ki ng’ se‘ fe Re lojojumo

   Gba mba fi ‘gbagbo sunmole. 

Egbe: Gbana l‘okan mi o korin...


4. Gba mo ba pari ise mi 

   Ti mo koja odo 

   Oluwa jo jek’okan mi 

   Le ba O gbe titi

   Ki nko ‘hun ti mo nihin

   Bi ‘fe Re ti po si mi to.

Egbe: Gbana l‘okan mi o korin 

      Labe agbelebu

      Nitori ‘simi dun l'ese Krist' 

      Gba mo fi ‘gbagbo re 'le

      Gba mo fi ‘gbagbo re 'le. Amin

English »

Update Hymn