HYMN 436

S.S. &S 610 (FE 560)
"Jesu wipe, e ma to mi lehin"
- Marku 1:171. MO fi gbogbo re fun Jesu, 

   Patapata l’aiku ‘kan

   Ngo ma fe, ngo si gbekele 

   Ngo si ma ba gbe titi. 

Egbe: Mo fi gbogbo re, Mo fi gbogbo re 

      Fun O, Olugbala mi, ni 

      Mo fi won sile.


2. Mo fi gbogbo re fun Jesu, 

   Mo si wole lese Re,

   Mo fi afe aiye sile

   Jesu, Jo gba mi wayi,

Egbe: Mo fi gbogbo re...


3. Mo fi gbogbo re fun Jesu, 

   Jesu se mi ni Tire

   Jek’ Emi Mimo s’eleri 

   Pe, O si je t’emi na. 

Egbe: Mo fi gbogbo re...


4. Mo fi gbogbo re fun Jesu, 

   Mo f’ara mi f'Oluwa

   F’ife at‘agbara kun mi 

   Si fun mi n’ibukun Re. 

Egbe: Mo fi gbogbo re...


5. Mo fi gbogbo re fun Jesu, 

   Okan mi ngbona wayi

   A! ayo igbala kikun

  Ogo ni f’oruko Re. 

Egbe: Mo fi gbogbo re...


6. Mo fi gbogbo re fun Jesu, 

   Mo f’ojo aiye mi fun 

   K’o ma so, k’o si ma to mi 

   K’o fi ‘nu mi se ‘bugbe. 

Egbe: Mo fi gbogbo re...


7. Kerubu pelu Serafu 

   Se Metalokan n’tire

   Fi Baba, Omo at’Emi 

   Se tire titi aiye.

Egbe: Mo fi gbogbo re, Mo fi gbogbo re 

      Fun O, Olugbala mi, ni 

      Mo fi won sile. Amin

English »

Update Hymn