HYMN 438

(FE 462)
"Ore mi Ii enyin ise" - John 15:141. ORE bi Jesu ko si l’aiye yi 

   On nikan l'ore otito

   Ore aiye yi le ko wa sile 

   Sugbon Jesu ko je gbagbe mi. 

Egbe: A! ko je gbagbe mi!

      A! ko je gbagbe mi!

      Sugbon Jeru ko je gbagbe mi.


2. Duro d‘Oluwa, ma siyemeji 

   Ohunkohun to wu ko le de 

   ‘Gbati o ro pin, 'ranwo Re yio de 

   Eni ‘yanu l'Oba Oluwa. 

Egbe: A! ko je gbagbe mi!...


3. Enyin Alagba at’Aladura 

   Ati gbogbo Egbe Ojise 

   Onidajo mbo gongo yio so 

   Awawi kan ko si lojo na.

Egbe: A! ko je gbagbe mi!...


4. Enyin Om’Egbe Akorin bile 

   Ati gbogbo Egbe Akorin 

   Olugbala mbo lati pin ere

   O daju pe ko je gbagbe mi. 

Egbe: A! ko je gbagbe mi!...


5. Ojo mbo t’ao dan ‘gbagbo nyin wo 

   Kerubu on Serafu t’aiye

   Ina l'ao ft dan ‘gbagbo nyin wo 

   T’eni to ba jona padanu.

Egbe: A! ko je gbagbe mi!...


6. Ogo fun Baba, Ogo fun Omo 

   Ogo si ni fun Emi Mimo

   Ao fi ogo fun Metalokan

   O daju pe ko je gbagbe mi.

Egbe: A! ko je gbagbe mi!

      A! ko je gbagbe mi!

      Sugbon Jeru ko je 

      gbagbe mi. Amin

English »

Update Hymn