HYMN 439

(FE 463) 
Tune: Oluwa fise Ran Mi Alleluyah1. OLUWA l’oluso mi

   emi ki o s’alaini

   Jesu l‘osugo agutan omo Re

   O mu mi sun ni papa oko tutu to dara 

   O tu ara ati okan mi lara. 

Egbe: Damuuso fun Baba

      Awa ma ridi jinle, Kabiyesi

      Messiah mimo jowo mase le

      mi Iodo Re

      Nipa ore‐ofe Re ki nle de 'be.


2. Bi mo tile nkoja lo larin afonifoji 

   T‘o kun fun banuje at' opo ‘damu 
 
   Emi ki o si beru ohunkohun to le de 

   Tori Oluwa ogo wa pelu mi.

Egbe: Damuuso fun Baba...


3. Iwo fun mi li onje loju awon ota mi 

   O da ororo ‘fe Re simi lori

   Ire anu at‘ayo yo ma ba mi gbe titi 

   Ngo si ma yin O Oluwa titi lai. 

Egbe: Damuuso fun Baba...


4. Olorun aiyeraiye to da orun at‘aiye 
 
   Awa juba Re eleda alaye

   F‘anu Re lori awn eda owo Re laiye 

   F’abo to fi nbo wa ni ojo gbogbo. 

Egbe: Damuuso fun Baba...


5. A f'ogo f’oruko Re, 

   Jehovah mimo loke

   Jesu omo mimo to ra wa pada 

   A f'ogo f'Emi mimo to so 

  wa d‘eni iye
 
   Ogo f’ologo Metalokan lailai.

Egbe: Damuuso fun Baba

      Awa ma ridi jinle, Kabiyesi

      Messiah mimo jowo mase le

      mi Iodo Re

      Nipa ore‐ofe Re ki nle de 'be. Amin

English »

Update Hymn