HYMN 440

C.M.S 313. H.C 283 6s. 4s (FE 464) 
"Oju wa nwo Oluwa Olorun wa"
- Ps. 123:21. IGBAGBO mi wo O 

   Iwo Odagutan, 

   Olugbala,

   Jo gbo adura mi 

   M'ese mi gbogbo lo 

   K'erni lat’oni lo 

   Si je Tire.


2. Ki ore-ofe Re 

   F'ilera f'okan mi 

   Mu mi tara

   B'Iwo ti ku fun mi 

   A! k’ife mi si O

   K'o ma gbona titi! 

   B'ina iye.


3. Gba mo nrin l’okunkun 

   Ninu ibinuje

   S'amona mi 

   M'okunkun lo loni

   Pa ‘banuje mi re 

   Ki nma sako kuro 

   Li odo re.


4. Gbati aiye ba pin 

   T‘odo tutu iku 

   Nsan lori mi 

   Jesu, ninu ife

   Mu k‘ifoya mi lo 

   Gbe mi d’oke orun 

   B’okan t’ara. Amin

English »

Update Hymn