HYMN 441

7s 6s (FE 465) 
"Awon enia mi yio mo oruko mi"
-Isa.52:6
Tune: Ojo ayo l'eyi je1. GBOGBO enyin Onigbagbo 

   To wa lode aiye 

   Babalawo gbe ‘fa wa

   O tun d’Aladura.

Egbe: E yi pada

      Ojo ‘dajo de tan

      E yi pada, e sunmo Olorun.


2. Pupo abogi bo ‘pe 

   Fori bale f’Oba 

   Nwon si tun jeri Kristi 

   Niwaj’onigbagbo.

Egbe: E yi pada...


3. Oro Olugbala se, 

   Lori gbogbo aiye 

   Wipe gbogbo ekun ni 

   Yio wole fun mi. 

Egbe: E yi pada...


4. Sib’awon onigbagbo 

   Gb'ohun asan dani 

   T'o ni ohun ‘dile ni 

   Emi ko le s'aise. 

Egbe: E yi pada...


5. ltiju pupo yio wa 

   F’awon onigbagbop 

   At'awon onimale 

   Gb'onifa ba wole. 

Egbe: E yi pada...


6. Okunrin at’obinrin 

   T’o wa nin’Egbe yi 

   Ise po pupo l’oko 

   Tal‘awa yio ran lo. 

Egbe: E yi pada...


7. O seun omo rere 

   L’ohun ‘kehin yio je 

   F'awon to s‘olotito 

   ‘Nu Egbe Kerubu. 

Egbe: E yi pada...


8. E lo kuro lodo mi 

   Emi ko mo nyin ri 

   L’ohun ikehin yio je 

   F‘awon alaigbagbo. 

Egbe: E yi pada...


9. Jehovah Jire Baba 

   Jowo pese fun wa 

   Jehovah Nisi Baba 

   Pa wa mo de opin.

Egbe: E yi pada

      Ojo ‘dajo de tan

      E yi pada, e sunmo 

      Olorun. Amin

English »

Update Hymn