HYMN 442

H.C. 281 C.M (FE 466) 
"Awon Aposteli si wi fun Oluwa pe,
Busi igbagbo wa" - Luku 17:51. A ba le n’igbagbo aye 

   B’o ti wu k'ota po 

   Igbagbo ti ko je mira 

   Fun aini at’osi.


2. Igbagbo ti ko je rahun

   L'abe ibawi Re 

   Sugbon ti nsimi l’Olorun

   Nigba ibanuje


3. Igbagbo ti ntan siwaju
 
   Gbat' iji 'ponju de

   Ti ko si je siyemeji

   N'nu wahala gbogbo.


4. Igbagbo ti ngb'ona toro

   Titi emi o pin

   Ti y'o si f'imole orun

   Tan akete iku.


5. Jesu f’igbagbo yi fun mi 

   Nje b’o ti wu k‘o ri

   Lat'aiye yi lo ngo l’ayo 

   Ilu orun rere. Amin

English »

Update Hymn