HYMN 45

OKAN MIMO (FE 62)
“Da okan mimo sinu mi, Olorun"
- Ps. 51:10


1. MO ntoro nkan lodo Kristi, 

   'Tori ere po lona mi,

   Yala pe lomi tab'ina

   Sa we mi mo, sa we mi mo. 

Egbe: Jo, we mi mo-t'ara t'okan 

      Ngo ko ina - bo ba gba be 

      Ona-kona Io dun mo mi,

      K ‘ese sa ku ‘nu okan mi.


2. B'o ba f‘iran didan han mi 

   Ngo dupe inu mi yio dun 

   Sugbon okan t'o mo gara 

   Ni mo fe ju, ni mo fe ju. 

Egbe: Jo, we mi mo...


3. Nigbati okan mi ba mo, 

   Iran didan yio han si mi, 

   Nitori okukun su bo 

   Iran orun, Iran orun.

Egbe: Jo, we mi mo...


4. Mo ndu ki nsa f'ona ese 

   Ki nsi yago f’ero ese 

   B‘ijakadi mi ti to yi, 

   Sibe nko mo, sibe nko mo.

Egbe: Jo, we mi mo... Amin 

English »

Update Hymn