HYMN 451
H.C 294 6. 8s (FE 476)
"A fi ipile Re sole lori apata"
- Matt.7:25
1.  IGBAGBO mi duro lori
     Eje at’ododo Jesu
     Nko je gbekele ohun kan
     Lehin oruko nla Jesu.
Egbe:  Mo duro le Krist' Apata 
           Ile miran, Iyanrin ni.
2.  B’ire-ije mi tile gun 
     Or’ofe Re ko yipada 
     B’o ti wu k’iji na le to 
     Idakoro mi ko ni ye. 
Egbe:  Mo duro le Krist' Apata...
3.  Majemu ati eje Re
     L’emi o romo b’ikun mi de 
     Gba ko s’alati lehin mo 
     O je ireti nla fun mi.
Egbe:  Mo duro le Krist' Apata...
4.  Gbat' ipe kehin ba si dun
     A! mba le wa ninu Jesu
     Ki nwo ododo Re nikan
     Ki nduro ni ‘waju ite.
Egbe:  Mo duro le Krist' Apata 
           Ile miran, Iyanrin ni.  Amin
English »Update Hymn