HYMN 457

H.C 304 6.10s (FE 482)
"Oluwa ni ipin mi n okan mi wi"
 - Ekun. 3:341. LALA mi po, nko ni ‘simi laiye 

   Mo rin jinna, nko r‘ibugbe laiye 

   Nikehin mo wa won laiya Eni 

   T’o n’owo Re, t'O si npe alare 

   Lodo Re, mo r’ile at’isimi 

   Mo si di Tire, On si di temi.


2. Ire ti mo ni, lat’odo Re ni 

   B’ibi ba de, o je b’o ti fe ni

   B’On j’ore, mi mo la bi nko ri je 

   L’aisi Re, mo tosi bi mo l’oro

   Ayida le de, ere tab’ofo

   O dun mo mi, bi 'm ba sa je Tire.


3. B’ayida de, mo mo ‐ on ki yida 

   Orun ogo ti ki ku, ti ki wo 

   O nrin lor’awosanma at’iji

   O ntanmole s'okukun enia Re 

   Gbogbo nkan le lo, ko ba mi n’nu je 

   Bi m’ba je Tire, ti On je temi.


4. A! laiye, nko mo idaji ‘fe Re; 

   Labo ni mo nri, labo ni mo nsin 

   ‘Gba mo ba f’oju kan loke lohun 

   Ngo feran Re po, ngo si yin jojo 

   Ngo wi larin egbe orin orun

   Bi mo ti je Tire, t’On je temi. Amin

English »

Update Hymn