HYMN 46

O.K. H.C 327, D.C.M (FE 63) 
"Oluwa gbo, Oluwa d’ariji" - Dan. 9:19


1. GB'ADURA wa, Oba aiye,

   ‘Gbat’a wole fun O 

   Gbogbo wa nkigbe n‘irele 

   A mbebe fun anu

   T’iwa l’ebi, tire l'anu

   Mase le wa pada,

   Sugbon gbo ‘gbe wa n'ite Re, 

   Ran adura wa Iowa.


2. Ese awon baba wa po 

   Tiwa ko si kere, 

   Sugbon lati irandiran 

   Lo ti f'ore Re han 

   Nigba ewu, b'omi jija 

   Yi ilu wa yi ka

   lwo la nwo ta si nkepe 

   K'a ma r'iranwo Re.


3. L'ohun kan gbogbo wa wole 

   L‘abe iyonu Re,

   Gbogbo wa njewo ese wa, 

   A ngbawe fun ‘Ie wa

   F'oju anu wo aini wa,

   Bi a ti nkepe O! 

   Ma fi ‘dajo Re ba wa wi,

   Da wa si lanu Re. Amin

English »

Update Hymn