HYMN 461

t.C.M.S 591 S. 165 P.M (FE 486)
Ohun Orin: Oluwa emi sa ti gbohun Re
"Fi ipile re sole Iori apata" - Matt.7:251. MO fi gbagbo ba Olorun mi rin 

   Ti ngo fi de ‘te ogo

   Jowo Oluwa se mi ni Tire

   K’emi r'oju rere Re. 

Egbe: Fa mi mora, mora Oluwa

      S'ibi agbelebu t’oku 

      Fa mi mora, mora Oluwa 

      S’ibi eje Re t'o n'iye.


2. Nin'egba mefa nin' eya Lefi 

   A f'edidi sami won, 

   Jehofa_Jire, k'O le ka wa kun 

   Awon ‘yanfe Re ‘saju.

Egbe: Fa mi mora...


3. Nin’Egba mefa eya Manase 

   A f'edidi sami won 

  Oluwa jowo k’a le f’edidi 

  Sami s'Egbe Serafu (Kerubu).

Egbe: Fa mi mora...


4. Nin’ egbe mefa eya Josefu
 
   A f 'edidi sami won 

   Jehofa-Nassi K‘O le f'edidi 

   Semi s’Egbe Kerubu (Serafu).

Egbe: Fa mi mora...


5. Oro Jehovah ko le lo l'ofo, 

   Oro Baba ki sai se

   Ileri t'o se fun Abrahamu

   O mu se fun Isaaki. 

Egbe: Fa mi mora...


6. Enia Olorun kan ko le tosi 

   Nigbati aiye ti se

   Ma je ki ebi oro at‘ale

   P’awon Egbe Serafu.

Egbe: Fa mi mora, mora Oluwa

      S'ibi agbelebu t’oku 

      Fa mi mora, mora Oluwa 

      S’ibi eje Re t'o n'iye. Amin

English »

Update Hymn