HYMN 463

C.M.S 322, H.C 285 DCM (FE 488)
"E tetilele ki e wa sodo Mi”
- Isaiah 55:31. MO gbohun Jesu t’o wipe 

   ‘Wa simi lodo Mi,

   Gbe ori re, ‘wo alare

   Le okan aiya Mi’

   Nin‘aro on ibinuje

   Ni mo to Jesu wa,

   O je ib’isimi fun mi 

   O si mu ‘nu mi dun.


2. Mo gbohun Jesu t’o wipe 

   ‘Iwo ti ongbe ngbe 

   Ngo f’omi’ye fun O lofe 

   Bere, mu k'o si ye‘

   Mo to Jesu wa, mo si mu, 

   Ninu omi ‘ye na; 

   Okan, mi tutu, o soji

   Mo d’alaye n'nu Re.


3. Mo gbohun Jesu t’o wipe 

   “Mole aiye l’Emi;

   Wo mi, Emi ni orun re, 

   Ojo re y’o dara’

   Mo wo Jesu, emi si ri, 

   B’orun ododo mi, 

   Ninu ‘mole yi l’emi o rin 

   Tit’ ajo mi y'o pin. Amin

English »

Update Hymn