HYMN 464

C.M.S 312 H.C 308, 8s. 7s (FE 489) 
"E tujuka, Emi ni, e mase beru"
- Matt. 14:271. N'IRUMI at'iji aiye 

   Mo gbo ohun itunu kan 

   O nso si mi l‘eti wipe 

   Emi ni, mase beru.


2. Emi l’o we okan re mo 

   Emi l'o mu ki o riran 

   Emi n'oiye imole re 

   Emi ni, mase beru.


3. Awon igbi omi wonyi

   Ti f’agbara won lu mi ri, 

   Nwon ko le se o n’ibi mo; 

   Emi ni, mase beru.


4. Mo ti mu ago yi lekan, 

   ‘Wo ko le mo kikoro re, 

   Emi ti mo bi o ti ri 

   Emi ni: mase beru.


5. Mo pe, l‘ or'eni arun re, 

   Oju mi ko ye l‘ara re, 

   lbukun mi wa l‘ori re, 

   Emi ni, mase beru.


6. Gbat’emi re ba pin laiye, 

   T’awon t’orun wa pade re, 

   ‘Wo o gbohun kan t’o mo pe, 

   Emi ni, mase beru. Amin

English »

Update Hymn