HYMN 465

H.C 287 t.H.C 309 (FE 490)
P.M 6s. 8s
"Emi Ii Oluwa, Emi ko yipada " 
- Mal. 3:61. NIHIN l'ayida wa

   Ojo, erun, nkoja

   Ile ni nyan, ti o si nsa

   ‘Tana dada si nku

   Sugbon oro Jesu duro

   ‘Ngo wa pelu re' ni On wi.


2. Nihin l’ayida wa 

   L’ona ajo orun

   N‘nu gbogbo ‘reti, at’ eru

   N’nu ‘fe s’Olorun wa 

   A nsaika oro yi si po!

  ‘Ngo wa pelu re’ ni On wi.


3. Nihin l’ayida wa 

   Sugbon l’arin eyi

   L’arin ayidayid’ aiye 

   Okan wa ti ki yi

   Oro Jehofa ki pada

   ‘Ngo wa pelu re’ ni On wi.


4. Ona alafia

   Immanueli wa

   Majemu ti ore-ofe

   Lai nwon ki yipada

   ‘Nki yipada l’oro Baba 

   ‘Mo wa pelu re’ ni On wi. Amin

English »

Update Hymn