HYMN 468

t.9B 466 (FE 493)
"lwo ko gbodo ni Olorun miran” 
- Eks. 30:111. OLORUN kan lo to k'a sin

   K'a si feran Re l‘afetan

   A ko gbodo bo orisa

   Nitori ohun asan ni.

Egbe: K’a ranti pe lati ri igbala

      O to ka p’ofin mo 

      Ti Olorun ti so fun wa 

      Ti Olorun ti so fun wa.


2. Kerubu pelu serafu 

   Feran omonikeji re 

   Ife ni awon angeli

   Ni nwon fi sin Baba loke. 

Egbe: K’a ranti pe lati ri...


3. Baba aladura mura 

   Lati pad’awon kerubu 

   Ade ogo yio je tire 

   T'omo araiye ko le gba. 

Egbe: K’a ranti pe lati ri...


4. Ileri to se fun Mose

   Ni ori oke Sion

   T’ope On yio wa pelu re 

   Lati ko wa de le Kenani.

Egbe: K’a ranti pe lati ri...


5. Agbagba merinlelogun 

   Ajuba oruko nla nyin 

   Ati eda ‘laye merin 

   Ke s'amin si adura wa. 

Egbe: K’a ranti pe lati ri...


6. Jehovah Jire Oba wa 

   Gbadura Egbe Kerubu 

   Jehovah Nissi Baba wa 

   Metalokan gbadura wa.

Egbe: K’a ranti pe lati ri igbala

      O to ka p’ofin mo 

      Ti Olorun ti so fun wa 

      Ti Olorun ti so fun wa. Amin

English »

Update Hymn