HYMN 469
1.  GBEKELE l'ojoojumo
     Gbekele n’igba ‘danwo 
     B’igbagbo tile kere 
     Gbekele Jesu nikan. 
Egbe:  Gbekele nigba gbogbo 
           Gbekele I'ojoojuma 
           Gbekele l'onakona 
           Gbekele Jesu nikan.
2.  Emi Re n tan imole
     Si okan okunkun mi
     Lowo Re n ko le subu 
     Gbekele Jesu nikan 
Egbe:  Gbekele nigba gbogbo... 
3.  B’ona ba mo, no ko’rin
     B’o ba di, n o gbadura 
     Laarin ewu n o ke pe E 
     Gbekele Jesu nikan. 
Egbe:  Gbekele nigba gbogbo... 
4.  Gbekele titi dopin
     Titi aye yoo koja
     Ta o si de ‘nu ogo
     Gbekele Jesu nikan. 
Egbe:  Gbekele nigba gbogbo 
           Gbekele I'ojoojuma 
           Gbekele l'onakona 
           Gbekele Jesu nikan.  Amin
English »Update Hymn