HYMN 470


H.C 282 t.H.C 59 6. 8s (FE 495) 
“Alabukun li awan ti ko ri mi sugbon
ti nwon si gbagbo" - John.20:291. Om’Olorun a ko ri O

   Gba t'o wa s'aiye iku yi 

   Awa ko ri ibugbe Re

   Ni Nasareti ti a gan

   Sugbon a gbagbo p’ese Re 

   Ti te ita re kakiri.


2. A ko ri O lori igi 

   T'enia buburu kan O mo 

   A ko gbo Igbe Re, wipe 

  Dariji won, tor’ aimo won 

  Sibe, a gbagbo pe'ku Re 

  Mi aiye, o si m'orun su.


3. A ko duro leti boji 

   Nibiti a gbe te O si

   A ko joko ‘na yara ni

   A ko ri O loju ona

  Sugbon a gbagbo p’angeli 

  Wipe ‘Iwo ti ji dide.


4. A ko r’awon wonni t’o yan 

   Lati ri’goke r’orun Re

   Nwon ko fi iyanu woke

   Nwon si f 'eru dojubole

   Sugbo a gbagbo pe nwon ti ri O 

   Bi O ti ngoke lo s'orun.


5. Iwo njoba l’oke loni

   ‘Wo si nbukun awon Tire 

   Imole ago Re ko tan

   Si aginju aiye wa yi 

   Sugbon, a gba oro re gbo 

   Jesu, Olurapada wa. Amin

English »

Update Hymn