HYMN 471

C.M.S 326 C.M. (FE 496) 
"Ipase Re ni a ko si mo”
- Ps. 77:191. ONA ara l’Olorun wa, 

   Ngba sise Re laiye,

   A nri ‘pase Re l’or’okun 

  O ngun igbi l’esin.


2. Ona Re, enikan ko mo 

   Awamaridi ni

  O pa ise ijinle mo 

  Oba awon oba.


3. Ma beru mo, enyin mimo 

   Orun t’o su be ni

   O kun fun anu yio rojo 

   lbukun sori nyin.


4. Mase da Oluwa l’ejo 

   Sugbon gbeke re le 

   Gbati o ro pe O binu 

   Inu Re dun si o.


5. Ise Re fere ye wa na 

   Y’o ma han siwaju

  Bi o tile koro loni

  O mbo wa dun l’ola.


6. Afoju ni alaigbogbo

  Ko mo ‘se Olorun

  Olorun ni Olutumo 

  Y’o m’ona Re ye ni. Amin

English »

Update Hymn