HYMN 477

(FE 503)
Tune: Jesu mo wa sodo Re1. OLUWA jowo pa wa mo 

   Iwo l’awa gbekele

   Okan wa wi f ’Oluwa pe 

   Iwo li Olorun wa.

Egbe: A ko ni ‘re kan lehin Re Baba 

      Iwo l’awa gbekele 

      Mase fi wa sile f’ota

     K’asegun n’ile l’ode.


2. S’awon enia mimo Re

   Ani s’awon olola

   Bi eniti didun ‘nu wa

   Yio, ma wa titi lailai.

Egbe: A ko ni ‘re kan lehin... 


3. Ibinuje awon ti nsa 

   T’Olorun miran yio po 

   Ebo ohun min’eje won 

   L’emi ki yio ta sile.

Egbe: A ko ni ‘re kan lehin... 


4. Oluwa n’ipin ini mi 

   Ati ipin ago mi

   Sewo lo mu la mi duro

   T’o ko je k’ota ba je.

Egbe: A ko ni ‘re kan lehin... 


5. Okun tita bo s‘odo mi

   Nibi t’o dara julo

   L‘otito mo fowo soya

   Pe mo ni ogun rere.

Egbe: A ko ni ‘re kan lehin... 


6. Emi o fi ‘bukun f’Oluwa 

   To fun mi ni imoran 

   Okan mi pelu sa nko mi 

   L’arin wakati oru.

Egbe: A ko ni ‘re kan lehin... 


7. Mo gb'Oluwa ka ‘waju mi 

   Nibi gbogbo l’aiye mi 

   Tori o wa lowo ‘tun mi

   A ki yio si mi nipo.

Egbe: A ko ni ‘re kan lehin... 


8. Torina n'nu mi se dun

   T'ogo mi si nyo jade

   Ara mi pelu yio simi

   Ni ‘re ti iye ailopin. 

Egbe: A ko ni ‘re kan lehin... 


9. O ki yio f'okan mi sile

   Li arin ipo oku

   Beni eni mimo tire

   Ki yipo idibaje.

Egbe: A ko ni ‘re kan lehin... 


10. Mo mo p‘o f’ona ‘ye han mi, 

    Waju re l'ekun ayo wa

    Li owo otun Re sa ni

    Didun 'nu mi wa lailai.

Egbe: A ko ni ‘re kan lehin... 


11. S’alabo Egbe Serafu 

    Ati Egbe Kerubu

    Awon to nsin O nitoto

   Nigun mererin aiye.

Egbe: A ko ni ‘re kan lehin... 


12. Eje ka f ’ogo fun Baba 

    Ati fun Omo pelu

    Je ka f’ogo f’Emi Mimo

    Metalokan Aiyeraiye.

Egbe: A ko ni ‘re kan lehin Re Baba 

      Iwo l’awa gbekele 

      Mase fi wa sile f’ota

     K’asegun n’ile l’ode. Amin

English »

Update Hymn