HYMN 479

S.S. & S 417 (FE 505) 
"Jesu Omo Dafidi, sanu fun wa"
 - Matt. 10:41. ANU Re, Oluwa, l‘awa ntoro 

   Ro jo Re le wa

   Eiye ti nfo at’era to nrin ‘le 

   Nri won lopolopo.

Egbe: Anu, Anu, Anu Re

      Baba wa orun

      L'awa ntoro

      Abiyamo ki gbagbe omo Re 

      Jesu ma gbagbe mi.


2. Orun l'osan nipa ase Re ni 

   At'osupa l’oru

   Igba ojo at‘igba ikore 

   Lowo re ni nwon wa.

Egbe: Anu, Anu, Anu Re...


3. Gbati esu at’ese ndode wa 

   Ikolu won soro 

   Logo asan arankan ti p’aiya 

   Oluwa gba wa la.

Egbe: Anu, Anu, Anu Re...


4. Dafidi ko le gbagbe anu Re 

   Niwaju Golayat,

   Danieli ‘nu iho Kiniun

   lwo lo ns’abo re.

Egbe: Anu, Anu, Anu Re...


5. lru anu wonyi l'awa ntoro 

   Ro ojo Re le wa
 
   Larin ota je ki awa ma gba 

   Fun iyin ogo Re.

Egbe: Anu, Anu, Anu Re...


6. Anu bi Batimeu afoju 

   L‘a ntoro lodo Re

   Ati gbogbo awon alailera

   Nwonri anu Re gba. 

Egbe: Anu, Anu, Anu Re...


7. Ayaba Esita ko le gbagbe 

   Lasiko ‘damu Re 

   Adura lo fi segun ota re 

   Olorun lo ja fun.

Egbe: Anu, Anu, Anu Re...


8. Ota ile ko le se o nibi 

   Gbeke re le Jesu

   Aje, oso ati alawirin 

   Nwon npete l’asan ni.

Egbe: Anu, Anu, Anu Re

      Baba wa orun

      L'awa ntoro

      Abiyamo ki gbagbe omo Re 

      Jesu ma gbagbe mi. Amin

English »

Update Hymn