HYMN 481

1. DURO lori ileri Kristi Oba

   L’ojo gbogbo K‘iyin Re gba aye kan 

   Ogo f’Olorun l‘oke em‘o korin 

   Duro lori ‘leri Olorun.

Egbe: Duro, duro, duro Iori

      ‘leri Jesu Olugbala

      Duro, duro, mo nduro

      lori 'Ieri Olorun.


2. Duro lori ileri ti ko le ye 

   Gba t’iji aye nja, ti 'yemeji de 

   Nipa Oro Olorun ni ngo bori 

   Duro lori ‘Ieri Olorun, 

Egbe: Duro, duro, duro Iori...


3. Duro lori ‘leri Kristi Oluwa

   Ki ‘fe ayeraye so yin po s’okan 

   J‘asegun nipa ‘gbara ida Emi 

   Duro lori ‘leri Olorun.

Egbe: Duro, duro, duro Iori...


4. Duro lor ileri, nko le kuna

   Te'ti sile lati gbo ipe Emi

   Ki nsimi l’Olugbala mi lohungbogbo 

   Duro lori ‘leri Olorun.

Egbe: Duro, duro, duro Iori

      ‘leri Jesu Olugbala

      Duro, duro, mo nduro

      lori 'Ieri Olorun. Amin

English »

Update Hymn