HYMN 482

S.S. 393 (FE 508)
"Anu nsan pupo, Iwo Oluwa po"
- Ps.86:51. OGO fun Jesu f'anu Re lofe

   Anu lofe, anu lofe,

   Elese anu nsan, fun o lofe

   Anu nsan pupo lofe

   Bi iwo ba fe lati gba a gbo

   Anu lofe, anu lofe 

   Iwo yio r'iye ainipekun gba

   Anu nsan pupo lofe.

Egbe: Jesu Olugbala nwa o kiri

      Nwa o kiri, nwa o kiri

      T'anu -t'anu t'ife lo fi npe o,

      O npe o, O nwa o kiri.


2.  Ese to nkiri lokiti ese?

   Anu lofe, anu lofe 

   Emi npe o jeje wipe wa 'le

   Anu nsan pupo lofe

   O nwa n'okun bi? A! wa si 'mole

   Anu lofe, anu lofe

   Jesu nduro yio gba o lale yi 

   Anu nsan pupo lofe.

Egbe: Jesu Olugbala nwa o kiri...


3.  Ro ti ore, suru, ati ife re

   Anu lofe, anu lofe 

   O bebe fun o lodo Baba loke

   Anu nsan pupo lofe

   Wa ronupiwada fun lokan re

   Anu lofe, anu lofe

   Ma banuje sugbon wa b'o ti ri

   Anu nsan pupo lofe.

Egbe: Jesu Olugbala nwa o kiri...


4.  Nje anu wa fun gbogb' eni gbagbo

   Anu lofe, anu lofe 

   Wa k'o si gba 'bukun nisisiyi

   Anu nsan pupo lofe

   esu nduro, A! gbo b'O ti nkede

   Anu lofe, anu lofe

   Ro mo 'leri Re 'gba Oko Re gbo

   Anu nsan pupo lofe.

Egbe: Jesu Olugbala nwa o kiri

      Nwa o kiri, nwa o kiri

      T'anu -t'anu t'ife lo fi npe o,

      O npe o, O nwa o kiri. Amin

English »

Update Hymn