HYMN 485

6s 8s (FE 511)
"Jehovah Jire-Oluwa yio pese"
 - Gen. 22:141. OLUWA yio pese

   Fun gbogbo aini wa 

   Eni ko bi a bi

   Eni bi a tunla.

Egbe: Ese wa fun awon eiye 

      Ma kominu, ma kominu

      yio pese.


2. Oluwa yio pese

   lse rere fun wa

   lgba rere yio de

   Oja wa yio si ta.

Egbe: Ese wa fun awon eiye...


3. Oluwa yio pese 

   Opo oja yio de 

   Eni nra yio si ri 

   Eni nta yio si ta.

Egbe: Ese wa fun awon eiye...


4. Oluwa yio pese

   Alafia ara

   Alaisan yio dide

   Eni nku lo yio san.

Egbe: Ese wa fun awon eiye...


5. Oluwa yio pese

   Emi gigun fun wa 

   Angeli yio so wa

   A ko ni r’agbako.

Egbe: Ese wa fun awon eiye...


6. Oluwa yio pese 

   Tabi, tabi ko si 

   F'eni to ba gbagbo.

   Gbagbo tokan-tokan.

Egbe: Ese wa fun awon eiye...


7. Oluwa yio pese

   Awa maridi ni 

  Ju gbogbo wonyi lo

  Awa yio ba goke.

Egbe: Ese wa fun awon eiye...


8. Oluwa yio pese

   Gbogbo wa yio riran

   Aini ko ni si mo 

   Kedere l'a o mo.

Egbe: Ese wa fun awon eiye 

      Ma kominu, ma kominu

      yio pese. Amin

English »

Update Hymn