HYMN 486

C.M.S 428 H.C 431 S.M (FE 512)
"Bi olukuluku ti ri ebun gba" - 1Peter. 4:101. OHUN t'a fi fun O

   Tire ni Oluwa

   Gbogbo ohun ti a si ni 

   Owo Re loti wa.


2. Jek' a gba ebun Re

   Bi iriju rere

   Bi O si ti mbukun wa to

   Be l'a o fi fun O.


3. Opo ni ise nse

   Ti nson ko r'onje je 

   Opo l'o si ti sako lo

   Kuro l'agbo Jesu.


4. K'a ma tu ni ninu 

   K'a ma re ni l'ekun

   K'a ma bo alainibaba

   N'ise t'a ba ma se.


5. K’a tu onde siIe

   K‘a f‘ona iye han 

   K‘a ko ni Iona OIorun 

   B’iwa Krsisti lo ri.


6. A gba oro Re gbo

   Busi igbagbo wa

   Ohun t’a se fun eni Re 

   Jesu, a se fun O. Amin

English »

Update Hymn