HYMN 487

1. LATI 'nu ide ibanuje

   Jesu mo de, Jesu mo de 

   Mo wa gba omnira at’ayo 

   Jesu mo wa do Re 

   Alaisan, emi nfe iwosan 

   Alaini, so mi di oloro 

   Elese, mo wa si odo Re 

   Jesu, mo wa‘do Re.


2. Eni-tiju ati eIeya

   Jesu mo de, Jesu mo de 

   Mo wa jere nla n’nu iku Re 

   Jesu mo wa’do Re 

   Wo n'itunu fun ibanuje 

   Wo n‘isimi fun gbogbo iji 

   Jesu mo wa’do Re.


3. Ninu rudurudu aiye yi 

   Jesu mo de, Jesu mo de 

   Mo wa s'inu pipe ife Re 

   Jesu mo wa’do Re 

   Mu mi kuro n’nu ife ara 

   Kuro ninu aiye asan yi

   Ki nle wa fi’ye idi goke 

   Jesu mo wa’do Re.


4. N‘nu eru iku at‘iboji

   Jesu mo de, Jesu mo de 

   Mo wa s'inu ayo ile mi 

   Jesu mo wa'do Re

   Lati nu iho iparun nla 

   Sinu alafia t‘o jinle

   Lati wa w‘oju Re ologo 

   Jesu mo wa‘do Re. Amin

English »

Update Hymn