HYMN 488

8s 7s
Ma Toju Mi Jihofa Nla1. WO awon t'o wo ‘so ala 

   Won duro leti odo

   Won k‘eyin s'aye at‘esu 

   Won ntele Atebomi

   Won si nreti 

   Lati se ase Jesu.


2. Wo bi won ti duro l'eru 

   Sugbon pelu ireti

   Won mo pe Olugbala won 

   L‘O pase odo lilo

   Jordan tutu

   Sugbon igbagbo gbona.


3. Si wo awon arakunrin

   Egbon won ninu Jesu

   Wo bi won ti na’ wo ife

   Won sa ti dabi won ri, Nisisiyi 

   Won ny‘ayo idariji.


4. Lo, tele Olugbala yin 

   E f'oju igbagbo ri

   A! orun si, Emi Baba

   Si nke lat‘oke wipe

   Awon wonyi

   Ni ayanfe omo Mi. Amin

English »

Update Hymn