HYMN 489

(FE 515)
Tune: “Olorun gbogbo araiye"1. OLORUN opo arugbo 

   T’aiye ro pe ko le bimo mo 

   N‘Iwo se l‘ogo to bimo

   O si d’oju t’awon ota re.

Egbe: Gbo temi, gbo temi

      Gbo temi, Oba awimayehun

      Gbo temi, gbo temi

      Gbo temi, Oba awimayehun.


2. O s’arugbo di wundia 

   Olorun to la Serah lagan 

   Ko ku, ko sa O wa nibe 

   Baba, se ‘ranlowo wa loni. 

Egbe: Gbo temi, gbo temi...


3. Sarah fere ma tun le gba

   Pe'ru on tun le bimo mo

   Lo fi rerin ninu okan 

   Sugbon Olorun ko ka s'ese fun. 

Egbe: Gbo temi, gbo temi...


4. Okiki Olorun mi kan 

   Oju mi ko ri ‘ru eyi ri 

   T‘igi t’ope lo ndamuso 

   Fun iloyun Elisabeti. 

Egbe: Gbo temi, gbo temi...


5. Hihu agbado ki tase 

   Hihu oka ti tase

   Mase jek‘ arabinrin yi 

   Tase omo rere lodo Re.

Egbe: Gbo temi, gbo temi...


6, Baba, Omo, Emi Mimo 

   Ko s’awati ore lodo Re 

   Ma jek‘oso aje dina

   Lati f‘arabinrin yi l‘omo.

Egbe: Gbo temi, gbo temi

      Gbo temi, Oba awimayehun

      Gbo temi, gbo temi

      Gbo temi, Oba awimayehun. Amin

English »

Update Hymn