HYMN 491

8s 7s (FE 517)
Tune: Wo Oluwa l'awosanma1. EMI iwosan sokale wa

   Wa pelu agbara Re 

   Wa pelu ogo at'Ola Re 

   Wa pelu Ase Nla Re

Egbe: Wo iranse re san

      Fun ni alafia 

      Fun ni ara lile

      K'emi re s'owon loju Re.


2. Emi iwosan sokale wa 

   Dar'ese omo re ji

   Ki o ya omo Re si mimo 

   Ki ebe wa je itewogba. 

Egbe: Wo iranse re san...


3. Emi ti nji oku did e 

   Emi to ba Elisah sise 

   Emi to ba Elijah sise 

   Sokale l'agbara Re e. 

Egbe: Wo iranse re san...


4. Emi ti n gbe ro dide

   Emi to ba Peteru sise 

   Emi to ba Johanu sise 

   Sokale l'agbara Re e. 

Egbe: Wo iranse re san...


5. Emi ti nso oku d'alaye

   Emi to ba Mose sise 

   Orimolade Baba wa

   Wa pelu Ase Nla Re. 

Egbe: Wo iranse re san...


6. Emi to nla oju afoju

   Emi to nwo alarun san 

   Emi ti ns‘adete di mimo 

   Emi ti nsise iyanu nla. 

Egbe: Wo iranse re san...


7. Emi ti nwo asinwin san,

   Emi ti nporo ofa ota

   Emi ti nsegun agbara aje 

   Emi Ito Alafia.

Egbe: Wo iranse re san

      Fun ni alafia 

      Fun ni ara lile

      K'emi re s'owon loju Re. Amin

English »

Update Hymn